Exodus 7:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose ati Aaroni bá lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ọ̀pá náà di ejò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì ṣe bí OLÚWA ti pàṣẹ fún wọn, Árónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò.