Exodus 7:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọ fún un pé, ‘OLUWA, Ọlọrun àwọn Heberu rán mi sí ọ, pé kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, kí wọ́n lè sin òun ní aṣálẹ̀, sibẹ o kò gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún un pé, ‘OLÚWA Ọlọ́run àwọn Hébérù rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni ihà. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba.