Exodus 7:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó mú ọ̀pá rẹ̀, kí ó sì nà án sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ati sórí odò wọn, ati sórí adágún tí wọ́n gbẹ́, ati gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ yóo sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti; ati omi tí ó wà ninu agbada tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati tinú agbada tí wọ́n fi òkúta gbẹ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún Mósè, “Sọ fún Árónì, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Éjíbítì: Lórí àwọn odò kéékèèke àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi;’ wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Éjíbítì, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.”