Exodus 7:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose ati Aaroni ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA lójú Farao ati lójú gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Aaroni gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ó sì fi lu omi tí ó wà ninu odò Naili, gbogbo omi tí ó wà ninu odò náà sì di ẹ̀jẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃ bi OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; o si gbé ọpá na soke o si lù omi ti o wà li odò li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀; a si sọ gbogbo omi ti o wà li odò na di ẹ̀jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè àti Árónì sí ṣe gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Náìlì, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀.