Exodus 7:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ẹja tí ó wà ninu odò náà kú, odò sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò fi lè mu omi rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹja ti o wà li odò si kú; odò na si nrùn, awọn ara Egipti kò si le mu ninu omi odò na; ẹ̀jẹ si wà ni gbogbo ilẹ Egipti,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹja inú odò Náìlì sì kú, odò náà ń rùn gidigidi tí ó fi jẹ́ pé àwọn ará Éjíbítì kò le è mu omi inú rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà ni ibi gbogbo ni ilẹ̀ Éjíbítì.