Exodus 7:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn pidánpidán ilẹ̀ Ijipti lo ọgbọ́n idán wọn, àwọn náà ṣe bí Mose ati Aaroni ti ṣe, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn Farao túbọ̀ yigbì sí i, kò sì gbọ́ ohun tí Mose ati Aaroni wí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn alalupayida Egipti si fi idán wọn ṣe bẹ̃: àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Éjíbítì sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Fáráò sì yigbì ṣíbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ.