Exodus 7:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni n óo nawọ́ ìyà sí Ijipti, n óo sì kó àwọn ọmọ Israẹli, ìjọ eniyan mi, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ ìyanu ati ìdájọ́ ńlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ṣíbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Éjíbítì, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.