Exodus 8:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose ati Aaroni bá jáde kúrò níwájú Farao, Mose gbadura sí OLUWA pé kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà kúrò, gẹ́gẹ́ bí òun ati Farao ti jọ ṣe àdéhùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose ati Aaroni si jade kuro lọdọ Farao: Mose si kigbe si OLUWA nitori ọpọlọ ti o ti múwa si ara Farao.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí Mósè àti Árónì tí kúrò ní ìwájú Fáráò, Mósè gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí OLÚWA nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti ran sí Fáráò.