Exodus 8:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn pidánpidán náà sọ fún Farao pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí.” Ṣugbọn ọkàn Farao le, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn onídán sì sọ fún Fáráò pé, “Ìka Ọlọ́run ni èyí.” Ṣùgbọ́n àyà Fáráò sì yigbì, kò sì fetí sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ.