Exodus 8:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá tún sọ fún Mose pé, “Dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí o lọ dúró de ọba Farao bí ó bá ti ń jáde lọ sétí odò, wí fún un pé, kí ó gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí o sì ko Fáráò lójú bí ó ṣe ń lọ sí odò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni OLÚWA sọ: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó bá à lè sìn mi.