Exodus 8:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, èmi OLUWA yóo ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn eniyan mi ń gbé, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin má baà lè débẹ̀, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA ní ayé yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ́ na li emi o yà ilẹ Goṣeni sọ̀tọ, ninu eyiti awọn enia mi tẹ̀dó si, ti eṣinṣin ki yio sí nibẹ̀; nitori ki iwọ ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA lãrin ilẹ aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, èmi yóò ya ilẹ̀ Góṣénì sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, èmi ni OLÚWA, mo wà ni ilẹ̀ yìí.