Exodus 8:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose dá a lóhùn pé, “Kò ní tọ̀nà bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀; nítorí pé àwọn nǹkan mìíràn lè wà ninu ohun tí a óo fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa tí ó lè jẹ́ ìríra fún àwọn ará Ijipti. Bí a bá fi ohunkohun rúbọ tí ó jẹ́ ìríra lójú àwọn ará Ijipti, ṣé wọn kò ní sọ wá ní òkúta pa?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wipe, Kò tọ́ lati ṣe bẹ̃; nitori awa o fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ si OLUWA Ọlọrun wa: wò o, awa le fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ li oju wọn, nwọn ki yio ha sọ wa li okuta?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí OLÚWA Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Éjíbítì. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn kò ní sọ òkúta lù wá?