Exodus 8:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bá dáhùn pé, “Wò ó, ń óo jáde kúrò ní iwájú rẹ nisinsinyii, n óo sì lọ gbadura sí OLUWA, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin wọnyi lè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀la, kí wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati àwọn eniyan rẹ pẹlu ṣugbọn kí Farao má tún dalẹ̀, kí ó má wí pé àwọn eniyan Israẹli kò gbọdọ̀ lọ rúbọ sí OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wipe, Kiyesi i, emi njade lọ kuro lọdọ rẹ, emi o si bẹ̀ OLUWA ki ọwọ́ eṣinṣin wọnyi ki o le ṣi kuro lọdọ Farao, kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀, li ọla: kìki ki Farao ki o máṣe ẹ̀tan mọ́ li aijẹ ki awọn enia na ki o lọ rubọ si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí OLÚWA, awọn esinsin yóò fi Fáráò, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánílójú wa pé Fáráò kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí OLÚWA.”