Exodus 8:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóo máa gbá yìnìn ninu odò Naili, wọn yóo sì wọ inú ààfin rẹ ati yàrá tí ò ń sùn, wọn yóo gun orí ibùsùn rẹ, wọn yóo sì wọ ilé àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati ti àwọn eniyan rẹ. N óo dà wọ́n sinu ilé ìdáná ati sinu àwo tí wọ́n fi ń tọ́jú oúnjẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Odò yio si bi ọpọlọ jade li ọ̀pọlọpọ, nwọn o si goke, nwọn o si wá sinu ile rẹ, ati sinu ibùsun rẹ, ati sori akete rẹ, ati sinu ile awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu ãro rẹ, ati sinu ọpọ́n ìpo-iyẹfun rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Odò Náílì yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọ́. Wọn yóò gókè wá sí ààfin rẹ, àti yàrá rẹ ni orí ìbùsùn rẹ. Wọn yóò gòkè wá sí ilé àwọn ìjòyè rẹ àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ, àti sí ibi ìdáná rẹ, àti sí inú ìkòkò ìyẹ̀fun rẹ.