Exodus 8:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose dá Farao lóhùn pé, “Sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n gbadura fún ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati àwọn eniyan rẹ, kí Ọlọrun lè run gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ yín, ati ninu ilé yín; kí ó sì jẹ́ pé kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun Farao pe, Paṣẹ fun mi: nigbawo li emi o bẹ̀bẹ fun ọ, ati fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun awọn enia rẹ, lati run awọn ọpọlọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ki nwọn ki o kù ni kìki odò nikan?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sọ fún Fáráò pé, “Jọ̀wọ́ sọ fún mi ìgbà ti èmi yóò gbàdúrà fún ọ àti àwọn ìjòyè rẹ àti fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí bá lè lọ lọ́dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé yín tí wọn yóò sì wà nínú odò Náílì nìkan.”