Exodus 9:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun tún sọ fún Mose pé kí ó wọlé tọ Farao lọ, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sìn òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn le sìn mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Lọ sọ fún Fáráò, ‘Èyí ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ: “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí.”