Exodus 9:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose ati Aaroni bá bu eérú ninu ẹbu, wọ́n dúró níwájú Farao. Mose da eérú náà sókè sí ojú ọ̀run, eérú náà bá di oówo tí ń di egbò lára eniyan ati ẹranko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si bù ẽru ninu ileru, nwọn duro niwaju Farao; Mose si kù u si oke ọrun; o si di õwo ti o ntú jade pẹlu ileròro lara enia ati lara ẹran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Fáráò. Mósè sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran.