Exodus 9:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, yára ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn ẹran rẹ tí wọ́n wà ninu pápá síbi ìpamọ́, nítorí pé yìnyín yóo rọ̀ sórí eniyan ati ẹranko tí ó bá wà ní pápá, tí wọn kò bá kó wọlé, gbogbo wọn ni yóo sì kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi ranṣẹ, ki o si kó ẹran rẹ bọ̀, ati ohun gbogbo ti o ni ninu oko; nitori olukuluku enia ati ẹran ti a ba ri li oko, ti a kò si múbọ̀ wá ile, yinyin yio bọ lù wọn, nwọn o si kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pàṣẹ nísin yìí láti kó ẹran-ọ̀sìn yin àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’ ”