Exodus 9:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àjàkálẹ̀ àrùn yóo ti ọwọ́ òun OLUWA wá sórí gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní pápá, ati àwọn ẹṣin rẹ̀, ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ati àwọn ràkúnmí rẹ̀, ati àwọn agbo mààlúù rẹ̀, ati àwọn agbo aguntan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ọwọ́ OLUWA mbẹ lara ẹran-ọ̀sin rẹ ti mbẹ li oko, lara ẹṣin, lara kẹtẹkẹtẹ, lara ibakasiẹ, lara ọwọ́-malu, ati lara agbo-agutan wọnni: ajakalẹ-àrun buburu mbọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọwọ́ OLÚWA yóò mú àrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹsin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, rànkunmí, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín.