Exodus 9:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí Farao rí i pé òjò ti dá, ati pé yìnyín ati ààrá ti dáwọ́ dúró, ó tún dẹ́ṣẹ̀, ọkàn rẹ̀ tún le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Farao ri pe, òjo ati yinyin ati ãra dá, o ṣẹ̀ si i, o si sé àiya rẹ̀ le, on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Fáráò rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣè ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọkan Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ yigbì.