Ezekiel 1:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Báyìí ni ojú wọn rí: olukuluku wọn ní ojú eniyan níwájú, àwọn mẹrẹẹrin ní ojú kinniun lápá ọ̀tún, wọ́n ní ojú akọ mààlúù lápá òsì, wọ́n sì ní ojú ẹyẹ idì lẹ́yìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Niti aworan oju wọn, awọn mẹrẹrin ni oju enia, ati oju kiniun, niha ọtun: awọn mẹrẹrin si ni oju malu niha osì; awọn mẹrẹrin si ni oju idì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni ìrísí ojú àwa ẹ̀dá alààyè yìí: ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apa ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì.