Ezekiel 1:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nǹkankan wà láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè náà tí ó dàbí ẹ̀yinná tí ń jó. Ó ń lọ sókè sódò láàrin wọn bí ahọ́n iná. Iná náà mọ́lẹ̀, ó sì ń kọ mànàmànà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Niti aworan awọn ẹda alãye na, irí wọn dabi ẹṣẹ́ iná, ati bi irí inà fitila: o lọ soke ati sodo, lãrin awọn ẹda alãye na, iná na si mọlẹ, manamana si jade lati inu iná na wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná tọ́ọ̀sì. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀.