Ezekiel 1:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìrísí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ati bí a ti ṣe wọ́n nìyí: wọ́n ń dán yànrànyànràn bí òkúta kirisolite. Bákan náà ni àwọn mẹrẹẹrin rí. A ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí ìgbà tí àgbá meji bá wọ inú ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Irí awọn kẹkẹ́ na ati iṣẹ wọn dabi awọ̀ berili: awọn mẹrẹrin ni aworan kanna; irí wọn ati iṣẹ wọn dabi ẹnipe kẹkẹ́ li ãrin kẹkẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kírísólétì, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú.