Ezekiel 1:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń lọ, ìhà ibi tí wọn bá fẹ́ ninu ìhà mẹrẹẹrin ni wọ́n lè máa lọ láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yíjú pada, kí wọ́n tó máa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn lọ, nwọn fi iha wọn mẹrẹrin lọ, nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń yí bí wọ́n ti ń yí, wọ́n ń lọ tààrà síbi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè kọjú sí, kẹ̀kẹ́ wọn kò sì yapa bí àwọn ẹ̀dá náà ti n lọ.