Ezekiel 1:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọn bá ń lọ àwọn àgbá náà a máa yí lọ pẹlu wọn. Bí wọ́n bá dúró àwọn àgbá náà a dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn àgbá náà a gbéra nílẹ̀, nítorí pé ninu àwọn àgbá wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati wọnni lọ, wọnyi lọ; nigbati a gbe wọnni duro, wọnyi duro; ati nigbati a gbe wọnni soke kuro lori ilẹ a gbe kẹkẹ́ soke pẹlu wọn: nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ; bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́.