Ezekiel 1:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kinní kan bí awọsanma tí ó ń dán bíi Kristali wà lórí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ó tàn bo gbogbo orí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aworan ofurufu li ori ẹda alãye na dabi àwọ kristali ti o ba ni li ẹ̀ru, ti o nà sori wọn loke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí ó dàbí òfuurufú ràn bo orí àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí, ó ń tàn yinrin yinrin bí i yìnyín, ó sì ba ni lẹ́rù.