Ezekiel 1:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń lọ, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn, ó dàbí ariwo odò ńlá, bí ààrá Olodumare, bí ariwo ìdágìrì ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Bí wọ́n bá dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si lọ, mo gbọ́ ariwo iyẹ́ wọn, bi ariwo omi pupọ, bi ohùn Olodumare, ohùn ọ̀rọ bi ariwo ogun: nigbati nwọn duro, nwọn rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun. Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀.