Ezekiel 1:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìmọ́lẹ̀ tí ó yí i ká dàbí òṣùmàrè tí ó yọ ninu ìkùukùu lákòókò òjò. Bẹ́ẹ̀ ni àfiwé ìfarahàn ògo OLUWA rí. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo bá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ń sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi irí oṣumare ti o wà ninu awọsanma ni ọjọ ojo, bẹ̃ni irí didan na yika. Eyi ni aworan ogo Oluwa. Nigbati mo si ri, mo dojubolẹ, mo si gbọ́ ohùn ẹnikan ti nsọ̀rọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú ìkuukùu nígbà tí òjò bá rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká. Báyìí ni ìrísí ògo OLÚWA. Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.