Ezekiel 10:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọn tí ń lọ, ibikíbi tí ó bá wu àwọn Kerubu náà ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin tí wọ́n kọjú sí ni wọ́n lè lọ láì jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada, nítorí pé ibikíbi tí èyí tí ó wà níwájú bá kọjú sí ni àwọn yòókù máa ń lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn lọ, nwọn fi ihà wọn mẹrẹrin lọ, nwọn kò yipada bi nwọn ti nlọ, ṣugbọn ibi ti ori ba kọju si, nwọn a tẹle e; nwọn kò yipada bi nwọn ti nlọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojú kọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ síbi tí orí dojú kọ láì yà.