Ezekiel 10:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Kerubu bá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n gbéra nílẹ̀ lójú mi, bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àgbá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke, nwọn si fò kuro lori ilẹ li oju mi: nigbati nwọn jade lọ, awọn kẹkẹ wà li ẹgbẹ̀ wọn pẹlu, olukuluku si duro nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ilà-õrun ile Oluwa: ogo Ọlọrun Israeli si wà lori wọn loke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé OLÚWA, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn.