Ezekiel 10:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan lára àwọn Kerubu náà na ọwọ́ sí inú iná tí ó wà láàrin wọn, ó bù ú sí ọwọ́ ọkunrin aláṣọ funfun náà. Ọkunrin náà gbà á, ó sì jáde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kerubu kan si nà ọwọ́ rẹ̀ jade lati ãrin awọn kerubu si iná ti o wà li ãrin awọn kerubu, o si mu ninu rẹ̀, o si fi si ọwọ́ ẹniti o wọ aṣọ ọgbọ̀: ẹniti o gbà a; ti o si jade lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ síbi iná tó wà láàrin kérúbù yóòkù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbàá, ó sì jáde lọ.