Ezekiel 10:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo wòye, mo sì rí i pé àgbá mẹrin ni ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Kerubu náà: àgbá kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kerubu kọ̀ọ̀kan. Àwọn kẹ̀kẹ́ náà ń dán yinrinyinrin bí òkúta Kirisolite.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati mo si wò, kiye si i, awọn kẹkẹ mẹrin na niha awọn kerubu, kẹkẹ kan niha kerubu kan, ati kẹkẹ miran niha kerubu miran; irí awọn kẹkẹ na si dabi awọ̀ okuta berili.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì rí i pé kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àpapọ̀ àwọ̀ ewéko àti pupa rẹ́súrẹ́sú.