Ezekiel 11:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀mí gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. Àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan wà lẹ́nu ọ̀nà náà, mo rí i pé àwọn meji láàrin wọn jẹ́ ìjòyè: Jaasanaya, ọmọ Aṣuri, ati Pelataya, ọmọ Bẹnaya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ẸMI si gbe mi soke, o si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na ile Oluwa ti ilà õrun ti o kọju siha ilà-õrùn, si kiyesi i, ọkunrin mẹdọgbọn wà nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na; ninu awọn ẹniti mo ri Jaasania ọmọ Assuri, ati Pelatia ọmọ Benaia, awọn ijoyè awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé OLÚWA èyí tó dojú kọ ìlà oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) wá, mo rí Jáásáníà ọmọ Àsúrì àti Pélátíà ọmọ Bénáyà, tí wọ́n jẹ́ aláṣẹ àwọn ènìyàn.