Ezekiel 11:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA; nítorí pé ẹ kò rìn ninu ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣugbọn ẹ ti gba àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa: nitoriti ẹnyin kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni ẹnyin kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn ẹnyin ti hu ìwa awọn keferi ti o wà yi nyin ka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀ èdè tó yí yín ká.”