Ezekiel 11:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà wí fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní, bí mo tilẹ̀ kó wọn lọ jìnnà sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ ayé, sibẹsibẹ mo jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ tí wọ́n lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Bi mo tilẹ ti tá wọn nù réré lãrin awọn keferi; bi mo si ti tú wọn ka lãrin ilẹ pupọ, sibẹ emi o jẹ ibi mimọ́ kekere fun wọn ni ilẹ ti wọn o de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀ èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, n ó jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’