Ezekiel 11:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, wí fún wọn pé èmi, ‘OLUWA Ọlọrun ní n óo kó wọn jọ láti ààrin àwọn ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo fọ́n wọn ká sí, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Emi tilẹ kó nyin kuro lọdọ awọn orilẹ-ède; emi o si kó nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ká si, emi o si fun nyin ni ilẹ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, sọ pé: ‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì padà.’