Ezekiel 11:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi o ṣe ti awọn ti ọkàn wọn nrìn nipa ọkàn ohun irira ati ohun ẽri wọn, Emi o sẹsan ọ̀na wọn sori ara wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sórí wọn bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA Ọlọ́run wí.”