Ezekiel 11:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, àwọn Kerubu bá gbéra, wọ́n fò, pẹlu àgbá, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn; ìtànṣán ògo OLUWA Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke, pelu awọn kẹkẹ́ lẹgbẹ wọn, ogo Ọlọrun Israeli si wà lori wọn loke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lókè orí wọn.