Ezekiel 12:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọ̀n mi ni emi o si tẹ́ le e lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi: emi o si mu u wá si Babiloni, si ilẹ awọn ara Kaldea; kì yio si ri i, bẹ̃ni yio kú nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
N ó ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, N ó sì mú lọ sí Bábílónì, ní ilẹ̀ Kádíyà, ṣùgbọ́n kò ní fojú rí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí.