Ezekiel 12:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ti o yi i ka lati ràn a lọwọ, ati gbogbo ọwọ-ogun rẹ̀, ni emi o tuká si gbogbo afẹ̃fẹ, emi o si yọ idà le wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ (opá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀) ni N ó túká sí afẹ́fẹ́, n ó sì tún fi idà lé wọn kiri.