Ezekiel 12:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa, nigbati mo ba tú wọn ka lãrin awọn orilẹ-ède; ti mo ba si fọ́n wọn ká ilẹ pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wọn ó sì mọ̀ pé èmi ni OLÚWA láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo bá tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri.