Ezekiel 12:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o kù diẹ ninu wọn silẹ lọwọ idà, lọwọ iyàn, ati lọwọ ajakálẹ arùn; ki nwọn le sọ gbogbo ohun ẽri wọn lãrin awọn keferi, nibiti nwọn ba de; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n n ó ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, lọ́wọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè yìí. Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.”