Ezekiel 12:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, iwọ ọmọ enia, mura nkan kikolọ, ki o si kó lọ li oju wọn li ọsan; ki o si kó lati ipò rẹ lọ si ibomiran li oju wọn; o le ṣe pe nwọn o ronu, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, lọ́san gangan lójú wọn, kúrò láti ibi tí o wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, yóò yé wọn, wọn ó sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.