Ezekiel 12:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Mo gbé ẹrù mi jáde lọ́sàn-án gangan bí ẹrù ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, mo fi ọwọ́ ara mi dá odi ìlú lu, mo sì gba ibẹ̀ jáde lóru. Mo gbé ẹrù mi lé èjìká níṣojú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ṣe bi a ti paṣẹ fun mi: mo mu nkan mi jade li ọsan, bi nkan fun igbekùn, mo si fi ọwọ́ mi dá ogiri lu li aṣalẹ; mo gbe e jade ni wiriwiri alẹ, mo si rù u le ejika mi loju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún mi. Mo kẹ́rù mi jáde lọ́sàn án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbẹ́rù mi léjìká nínú òkùnkùn lójú wọn.