Ezekiel 13:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wí fún àwọn tí wọn ń kun odi náà ní ọ̀dà pé, òjò ńlá ń bọ̀, yìnyín ńlá yóo bọ́, ìjì líle yóo jà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wi fun awọn ti nfi amọ̀ aipò rẹ́ ẹ, pe, yio ṣubu; òjo yio rọ̀ pupọ; ati Ẹnyin, yinyín nla, o si bọ́; ẹfũfu lile yio si ya a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ̀ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, N ó sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀.