Ezekiel 13:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo wó ògiri tí ẹ kùn lẹ́fun, n óo wó o lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo hàn síta. Nígbà tí ó bá wó, ẹ óo ṣègbé ninu rẹ̀. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni emi o wo ogiri ti ẹnyin fi amọ̀ aipò rẹ́ lulẹ, emi o si mu u wá ilẹ, tobẹ̃ ti ipilẹ rẹ̀ yio hàn, yio si ṣubu, a o si run nyin li ãrin rẹ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò wó ògiri tí ẹ fi amọ̀ àìpò rẹ́, èyí tí ẹ fi ẹfun kùn lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ yóò hàn jáde. Nígbà ti odi náà wó palẹ̀, a ó sì run yín sínú rẹ̀, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.