Ezekiel 13:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára odi náà ati àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun. N óo wí fun yín pé, odi kò sí mọ́, àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun náà kò sì sí mọ́;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li emi o mu ibinu mi ṣẹ lori ogiri na, ati lori awọn ti o fi amọ̀ aipò rẹ ẹ, emi o si wi fun nyin pe, Ogiri na kò si mọ ati awọn ti o ti rẹ́ ẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni N ó ṣe lo ìbínú mi lórí odi yìí àti àwọn to fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, tí wọ́n sì fi ẹfun kùn ún. N ó sì sọ fún yín pé, “Kò sí odi mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó rẹ́ ẹ náà kò sí mọ́;