Ezekiel 13:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé, ‘Ègbé ni fún àwọn obinrin tí wọn ń so ẹ̀gbà òògùn mọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń ṣe ìbòjú fún gbogbo eniyan, kí ọwọ́ wọn lè ká eniyan. Ṣé ẹ̀ ń dọdẹ ẹ̀mí àwọn eniyan mi ni, kí ẹ lè dá àwọn ẹlòmíràn sí fún èrè ara yín?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Egbé ni fun awọn obinrin ti nrán tìmtim si gbogbo ìgbọnwọ, ti nwọn sì ndá gèle si ori olukuluku enia lati ṣọdẹ ọkàn! Ẹnyin o ṣọdẹ ọkàn awọn enia mi bi, ẹnyin o si gbà ọkàn ti o tọ̀ nyin wá là bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí o sọ pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Ègbé ni fún ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ń rán ìfúnpá òògùn sí ìgbọ̀nwọ́ àwọn ènìyàn, tí ẹ ń ṣe ìbòjú oríṣìíríṣìí fún orí oníkálukú ènìyàn láti sọdẹ ọkàn wọn: Ẹ̀yin yóò wa dẹkùn fún ọkàn àwọn ènìyàn mi kí ẹ sì pa ọkàn yin mọ́?