Ezekiel 13:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Mo kórìíra àwọn ẹ̀gbà ọwọ́, òògùn tí ẹ fi ń dọdẹ ẹ̀mí eniyan. N óo já wọn kúrò lápá yín, n óo sì tú àwọn ẹ̀mí tí ẹ dè sílẹ̀ bí ẹyẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ awọn tìmtim nyin, ti ẹnyin fi nṣọdẹ ọkàn nibẹ lati mu wọn fò, emi o si yà wọn kuro li apá nyin, emi o si jẹ ki awọn ọkàn na lọ, ani awọn ọkàn ti ẹnyin ndọdẹ lati mu fò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nítorí náà báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Mo lòdì sí ìfúnpá òògùn tí ẹ fi ń ṣọdẹ ọkàn ènìyàn káàkiri bí ẹyẹ, Èmi yóò ya á kúrò lápá yín; Èmi yóò sì dá ọkàn àwọn ènìyàn tí ẹ ń ṣọdẹ sílẹ̀.