Ezekiel 13:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo ya ìbòjú yín kúrò, n óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín. Wọn kò ní jẹ́ ohun ọdẹ lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gèle nyin pẹlu li emi o ya, emi o si gba awọn enia mi lọwọ nyin, nwọn kì yio si si lọwọ nyin mọ lati ma dọdẹ wọn; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò ya àwọn ìbòjú yín, láti gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín, wọn kò sì ní jẹ́ ìjẹ fún yín mọ́. Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.